1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jésù ńrìn ní Gálílì: nítorí tí kò fẹ́ẹ́ rìn ní Jùdéà, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa.
2 Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan.
3 Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhín-ínyìí, kí o sì lọ sí Jùdéà, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fí iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé.
4 Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkáarẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.”