3 Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhín-ínyìí, kí o sì lọ sí Jùdéà, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fí iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé.
4 Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkáarẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.”
5 Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbàágbọ́.
6 Nítorí náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Àkókò gan-an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín.
7 Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.
8 Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.”
9 Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Gálílì síbẹ̀.