34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”
35 Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárin àwọn Hélénì tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Hélenì bí.
36 Ọ̀rọ̀ kí ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”
37 Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jésù dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òrùgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.
38 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé-mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”
39 (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fúnni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jésù lógo.)
40 Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”