39 (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fúnni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jésù lógo.)
40 Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”
41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kírísítì náà.”Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kírísítì yóò ha ti Gálílì wá bí?
42 Ìwé-mímọ́ kò ha wí pé, Kírísítì yóò ti inú irú ọmọ Dáfídì wá, àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú tí Dáfídì ti wá?”
43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàárin ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.
44 Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.
45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”