45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”
46 Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”
47 Nítorí náà àwọn Farisí dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí?
48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisí ti gbà á gbọ́ bí?
49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”
50 Nikodémù ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,
51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”