5 Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbàágbọ́.
6 Nítorí náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Àkókò gan-an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín.
7 Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.
8 Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.”
9 Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Gálílì síbẹ̀.
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀.
11 Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”