1 Jésù sì lọ sí orí òkè Ólífì.
2 Ó sì tún padà wá sí tẹ́ḿpìlì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.
3 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú ní ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrin.
4 Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà,
5 Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”
6 Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.