13 Nítorí náà àwọn Farisí wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”
14 Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.
15 Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.
16 Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.
17 A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.
18 Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rí mi.”
19 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”