19 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”
20 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ḿpìlì: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.
21 Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ńlọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”
22 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”
23 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí
24 Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú níńu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
25 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe.