2 Ó sì tún padà wá sí tẹ́ḿpìlì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.
3 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú ní ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrin.
4 Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà,
5 Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”
6 Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.
7 Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ̀, ó nà rọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”
8 Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.