32 Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
33 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-Ọmọ Ábúráhámù ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”
34 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.
35 Ẹrú kì í sìí gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé
36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.
37 Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè nínú yín. Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀
38 Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”