4 Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà,
5 Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”
6 Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.
7 Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ̀, ó nà rọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”
8 Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.
9 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí-ọkan wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jésù nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàárin, níbi tí ó wà.
10 Jésù sì nà rọ́, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”