50 Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́.
51 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”
52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Ábúráhámù kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’
53 Ìwọ ha pọ̀ ju Ábúráhámù Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: tani ìwọ ń fi ara rẹ pè?”
54 Jésù dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ ǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe:
55 Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.
56 Ábúráhámù baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”