52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Ábúráhámù kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’
53 Ìwọ ha pọ̀ ju Ábúráhámù Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: tani ìwọ ń fi ara rẹ pè?”
54 Jésù dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ ǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe:
55 Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.
56 Ábúráhámù baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”
57 Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Ábúráhámù?”
58 Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi nìyìí.”