1 Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.
2 Àwọn Ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Olùkọ́, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”
3 Jésù dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a baà lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lara rẹ̀.
4 Àwa ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó ba ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.
5 Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”