2 Àwọn Ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Olùkọ́, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”
3 Jésù dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a baà lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lara rẹ̀.
4 Àwa ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó ba ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.
5 Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”
6 Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà pa ojú afọ́jú náà.
7 Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Sílóámù!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.
8 Ǹjẹ́ àwọn aládúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?”