24 Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ògo fún Ọlọ́run: àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́.”
25 Nítorí náà, ó dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀: Ohun kan ni mo mọ̀, pé mo tí fọ́jú rí, nísinsin yìí mo ríran.”
26 Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”
27 Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́: nítorí kínni, ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”
28 Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yin rẹ̀: ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mósè ni àwa.
29 Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eleyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”
30 Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sáà ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n Òun sáà ti là mí lójú.