57 Nígbà tí ọjọ́ Èlísabẹ́tì pé wàyí tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.
58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
59 Ó sì ṣe, ní ijọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sakaráyà, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.
60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é.”
61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.