60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é.”
61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.
64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.
65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Jùdéà.
66 Ó sì jẹ́ ohun ìyọnu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Irú ọmọ kínni èyí yóò jẹ́?” Nítirí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.