12 Tàbí bí ó sì bèèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekée?
13 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélóméló ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí-Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”
14 Ó sì ń lé ẹ̀mí ẹ̀sù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.
15 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Béélísébúbù olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
16 Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
17 Ṣùgbọ́n òun mọ ìrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di àhoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.
18 Bí Sàtánì sì yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.