36 Kí ẹ̀yin tìkárayín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé: pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.
37 Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń sọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
38 Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà.
39 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, (òun ìbá máa ṣọ́nà) kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun.
40 Nítorí náà kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú: Nítorí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”
41 Pétérù sì wí pé, “Olúwa, ìwọ́ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
42 Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ̀n fún wọn ní àkókò?