13 Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.
14 Olórí sínágọ́gù sì kún fún ìrúnnú, nítorí tí Jésù múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, Ijọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má se ní ọjọ́ ìsinmi.
15 Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbùso, kì í sì í fà á lọ mumi lí ọjọ́ ìsinmi.
16 Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í se ọmọbìnrin Ábúráhámù sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí sàtánì ti dè, sáà wò ó láti ọdún májìdínlógún yìí wá?”
17 Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ògo gbogbo tí ó ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ wá.
18 Ó sì wí pé, “Kíni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kíni èmi ó sì fi wé?
19 Ó dàbí hóró músítádì, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”