25 Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fù ú, tí ó bá sí ìlẹ̀kùn ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’
26 “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú.’
27 “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
28 “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.
29 Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà òòrùn, àti ìwọ̀-òòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
30 Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni ìwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”
31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhín-ín yìí: nítorí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ pa ọ́.”