3 Jésù sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisí pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbi kò tọ́?”
4 Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó sì mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
5 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”
6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé:
8 “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.
9 Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ àti òun bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní àyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.