5 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”
6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé:
8 “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.
9 Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ àti òun bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní àyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó t'oúnjẹ.
11 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbé ga.”