17 Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí sóńsó kan ti òfin kí ó yẹ̀.
18 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.
19 “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́:
20 Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lásárù, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju,
21 Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.
22 “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn ańgẹ́lì gbé e lọ sí oókan-àyà Ábúráhámù: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;
23 Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀.