21 Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.
22 “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn ańgẹ́lì gbé e lọ sí oókan-àyà Ábúráhámù: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;
23 Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀.
24 Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Ábúráhámù, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù, kí ó tẹ oríka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’
25 “Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lásárù ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.
26 Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’
27 “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi: