6 “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
7 Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti àmì kíní yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”
8 Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má báà mú yín sìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kírísítì náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.
9 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”
10 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.
11 Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.
12 “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.