52 Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?
53 Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójojúmọ́ ní tẹ́ḿpílì, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò ti yín ni èyí, àti agbára òkùnkùn.”
54 Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Pétérù tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè.
55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrin gbọ̀ngàn, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Pétérù jokòó láàrin wọn.
56 Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
58 Kò pẹ́ lẹ̀yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ọkùnrin yìí, Èmi kọ́.”