8 Ṣùgbọ́n ó mọ ìrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrin.” Ó sì dìde dúró.
9 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”
10 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì.
11 Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jésù.
12 Ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọnnì, Jésù lọ sí orí òkè lọ gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.
13 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní àpósítélì.
14 Símónì (ẹni tí a pè ní Pétérù) àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, Jákọ́bù àti Jòhánù, Fílípì àti Batolóméù.