16 Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!”
17 Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Jùdéà, àti gbogbo agbégbé tí ó yí i ká.
18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un.
19 Nígbà tí Jòhánù sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Jésù, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”
21 Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti àrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.
22 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yín rí, tí ẹ̀yín sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúkún-ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòsì ni à ń wàásù ìyìn rere.