40 Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.
41 Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jáírù, ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bá ẹṣẹ̀ Jésù, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun:
42 Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ó ń kú lọ.Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ń há a ní àyè.
43 Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, (tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn), tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un lára dá,
44 Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.
45 Jésù sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Pétérù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn há ọ ní ààyè, wọ́n sì ń bì lù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”
46 Jésù sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”