Róòmù 11:18-24 BMY

18 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò. Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí. Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò.

19 Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ”

20 Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́. Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́. Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi.

21 Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí.

22 Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.

23 Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.

24 Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn?