Róòmù 11:6-12 BMY

6 í ó bá sì ṣe pé nípa ti ore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí ore-ọ̀fẹ́ kì í ṣe ore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pe nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.

7 Kí ha ni? Ohun tí Isírẹ́lì ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìyànfẹ́ ti rí i, a sì ṣé àyà àwọn ìyókù le.

8 Èyí ni ìwé Mímọ́ ń wí nígbà tí ó sọ pé:“Ọlọ́run ti fi oorun kùn wọ́n,ó sì dí ojú àti etí wọn,wọn kò sì le ní ìmọ̀ Kírísítì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ síwọn.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì rí títí di ọjọ́ òní.”

9 Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé:“Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n,láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run.Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n,kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú.

10 Jẹ́ kí ojú wọn sókùnkùn, kí wọn má sì ṣe ríran.Sì jẹ́ kí ẹrù ńlá tẹ̀ wọ́n ba títí láéláé bí wọ́n ti ń rìn lọ.”

11 Ǹjẹ́ èyí fi hàn wí pé: Ọlọ́run àwọn Júù rẹ ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láéláé? Rárá o. Ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìgbàlà fún àwọn aláìkọlà. Nípa síṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn Júù jowú, kí wọn sì béèrè ìgbàlà Ọlọ́run náà fún ara wọn.

12 Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa.