Róòmù 11:8-14 BMY

8 Èyí ni ìwé Mímọ́ ń wí nígbà tí ó sọ pé:“Ọlọ́run ti fi oorun kùn wọ́n,ó sì dí ojú àti etí wọn,wọn kò sì le ní ìmọ̀ Kírísítì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ síwọn.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì rí títí di ọjọ́ òní.”

9 Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé:“Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n,láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run.Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n,kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú.

10 Jẹ́ kí ojú wọn sókùnkùn, kí wọn má sì ṣe ríran.Sì jẹ́ kí ẹrù ńlá tẹ̀ wọ́n ba títí láéláé bí wọ́n ti ń rìn lọ.”

11 Ǹjẹ́ èyí fi hàn wí pé: Ọlọ́run àwọn Júù rẹ ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láéláé? Rárá o. Ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìgbàlà fún àwọn aláìkọlà. Nípa síṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn Júù jowú, kí wọn sì béèrè ìgbàlà Ọlọ́run náà fún ara wọn.

12 Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa.

13 Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé Ọlọ́run ti yà mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà. Mo ń tẹnumọ́ ọn gidigidi mo sì ń rán àwọn Júù létí nípa rẹ̀ nígbákùúgbà tí ààyè bá wà.

14 Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn.