24 Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù:
25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:
26 Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́.
27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.
28 Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.
29 Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:
30 Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn.