9 Èmi sì ti wà láàyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú.
10 Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá.
11 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi.
12 Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.
13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.
14 Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
15 Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se.