Róòmù 8:31-37 BMY

31 Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

32 Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le sòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?

33 Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dárí jì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

34 Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run. Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀.

35 Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì? Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá. Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa? Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí?

36 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé:“Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà.Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa.”

37 Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa.