Róòmù 8:34-39 BMY

34 Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run. Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀.

35 Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì? Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá. Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa? Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí?

36 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé:“Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà.Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa.”

37 Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa.

38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kò sí ohunkóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ rẹ̀. Kì í se ikú tàbí ìyè. Àwọn ańgẹ́lì àti gbogbo agbára ọ̀run àpáàdì fún raarẹ̀ kò le ya ìfẹ́ Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ wa. Ìbẹ̀rù fún wa lónìí, wàhálà nípa ti ọjọ́ ọ̀la.

39 Tí ìsòro bá tilẹ̀ ga ju àwọ̀ sánmọ̀ lọ tàbí ní ìsàlẹ̀ omi, ohunkóhun kì yóò lágbára láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Jésù Kírísítì Olúwa fi hàn nígbà tí ó kú fún wa.