Àwọn Ọba Keji 11:14-20 BM

14 Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”

15 Jehoiada kò fẹ́ kí wọ́n pa Atalaya ninu ilé OLUWA, nítorí náà ó pàṣẹ fún àwọn olórí ogun, ó ní, “Ẹ mú un jáde, kí ó wà ní ààrin yín bí ẹ ti ń mú un lọ; ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà á là, pípa ni kí ẹ pa á.”

16 Wọ́n bá mú un gba ẹnu ọ̀nà tí àwọn ẹṣin máa ń gbà wọ ààfin, wọ́n sì pa á.

17 Jehoiada alufaa mú kí Joaṣi ọba ati àwọn eniyan dá majẹmu pẹlu OLUWA pé àwọn yóo jẹ́ tirẹ̀; ó sì tún mú kí àwọn eniyan náà bá ọba dá majẹmu.

18 Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o, wọ́n sì wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ ati àwọn ère rẹ̀ lulẹ̀. Wọ́n pa Matani, alufaa Baali, níwájú àwọn pẹpẹ náà.Jehoiada sì fi àwọn olùṣọ́ tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ sí ìtọ́jú ilé OLUWA.

19 Òun ati àwọn olórí ogun ati àwọn tí wọ́n ń ṣọ́ ọba ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin sin ọba láti ilé OLUWA lọ sí ààfin. Ọba gba ẹnu ọ̀nà àwọn olùṣọ́ wọlé, ó sì jókòó lórí ìtẹ́.

20 Gbogbo àwọn eniyan kún fún ayọ̀, gbogbo ìlú sì ní alaafia lẹ́yìn tí wọ́n ti fi idà pa Atalaya ní ààfin.