1 Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí.
2 Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
3 Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.”
4 Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi.
5 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.”Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?”Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.”
6 Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’
7 O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.