15 Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia.
16 Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé, Simiri ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ati pé ó ti pa á, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo Israẹli fi Omiri olórí ogun, jọba Israẹli ninu àgọ́ wọn ní ọjọ́ náà.
17 Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa.
18 Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná;
19 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀.
20 Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
21 Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri.