37 Wolii yìí rí ọkunrin mìíràn, o sì bẹ̀ ẹ́ pé, “Lù mí.” Ọkunrin yìí lù ú, lílù náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pa á lára.
38 Wolii yìí bá mú aṣọ kan, ó fi wé ojú rẹ̀. Ó yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má baà mọ̀ ọ́n, ó sì lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà de ìgbà tí ọba Israẹli yóo kọjá.
39 Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.
40 Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.”Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.”
41 Wolii náà sáré tu aṣọ tí ó fi wé ojú, lẹsẹkẹsẹ ọba sì mọ̀ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii ni.
42 Wolii náà bá wí fún ọba pé, “OLUWA ní, nítorí pé o jẹ́ kí ẹni tí mo ti pinnu láti pa sá lọ, ẹ̀mí rẹ ni n óo fi dípò ẹ̀mí rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan rẹ dípò àwọn eniyan rẹ̀.”
43 Ọba bá pada lọ sí ààfin rẹ̀ ní Samaria, pẹlu ìpayà ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.