20 Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.”
21 Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.”
22 Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”
23 Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.”
24 Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.”
25 Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.
26 Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA,