1 OLUWA ní kí Mose
2 sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí obinrin kan bá lóyún tí ó sì bí ọmọkunrin, ó di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
3 Tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, wọn yóo kọ ilà abẹ́ fún ọmọ náà.
4 Obinrin náà yóo wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹtalelọgbọn; kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohun mímọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ wá sinu ibi mímọ́, títí tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóo fi pé.
5 “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé obinrin ni ó bí, ọ̀sẹ̀ meji ni yóo fi wà ní ipò àìmọ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀; yóo sì wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹrindinlaadọrin.
6 “Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, kì báà ṣe fún ọmọkunrin tabi fún ọmọbinrin, yóo mú ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan wá sí ọ̀dọ̀ alufaa ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ fún ẹbọ sísun, kí ó sì mú yálà ọmọ ẹyẹlé tabi àdàbà wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.