Lefitiku 25 BM

Ọdún Keje

1 OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA.

3 Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀.

4 Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín.

5 Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀.

6 Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé,

7 ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ.

Ọdún Ìdásílẹ̀ ati Ìdápadà

8 “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta.

9 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín.

10 Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀.

11 Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú.

12 Nítorí pé, ọdún jubili ni yóo máa jẹ́ fun yín, yóo jẹ́ ọdún mímọ́ fun yín, ninu oko ni ẹ óo ti máa jẹ ohun tí ó bá so.

13 “Ní ọdún jubili yìí, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

14 Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ta ilẹ̀ fún aládùúgbò yín, tabi tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín.

15 Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín.

16 Tí ó bá jẹ́ pé ọdún pupọ ni ó kù, owó ilẹ̀ náà yóo pọ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ni, owó rẹ̀ yóo wálẹ̀; nítorí pé, iye ọdún tí ó bá lè fi gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ náà ni yóo wò láti ta ilẹ̀ náà.

17 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín, ṣugbọn ẹ bẹ̀rù Ọlọrun yín; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

Ìyọnu Tí Ó Wà ninu Ọdún Keje

18 “Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu.

19 Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu.

20 “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’

21 Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta.

22 Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ.

Dídá Nǹkan Ìní Pada

23 “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.

24 “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada.

25 Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada.

26 Bí ẹni náà kò bá ní ẹbí tí ó lè ra ilẹ̀ náà pada, ṣugbọn ní ọjọ́ iwájú, tí nǹkan bá ń lọ déédé fún un, tí ó sì ní agbára láti ra ilẹ̀ náà pada,

27 kí ó ṣírò iye ọdún tí ó ti tà á, kí ó sì san iye owó tí ó bá kù pada fún ẹni tí ó ta ilẹ̀ náà fún, lẹ́yìn náà kí ó pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

28 Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

29 “Bí ẹnìkan bá ta ilé kan ninu ìlú olódi, ó lè rà á pada láàrin ọdún kan lẹ́yìn tí ó ti tà á.

30 Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé.

31 Ṣugbọn a óo ka àwọn ilé tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí kò ní odi pọ̀ mọ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ wọn lé lórí. Ẹni tí ó ta ilẹ̀ lé rà wọ́n pada, ẹni tí ó rà á sì níláti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ nígbà tí ọdún jubili bá dé.

32 Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi lè ra gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà ní ààrin ìlú wọn pada nígbàkúùgbà.

33 Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli.

34 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé.

Yíyá Aláìní Lówó

35 “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì.

36 O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé.

37 O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè.

38 Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ.

Ìdásílẹ̀ Àwọn Ẹrú

39 “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú.

40 Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili.

41 Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀.

42 Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43 O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ.

44 Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin.

45 Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín.

46 Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín.

47 “Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín,

48 lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada.

49 Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada.

50 Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

51 Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada.

52 Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san.

53 Ọkunrin tí ó ta ara rẹ̀ yìí yóo dàbí iranṣẹ tí à ń gbà lọdọọdun sí ẹni tí ó rà á; ẹni tí ó rà á kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un lójú rẹ̀.

54 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ra ẹni náà pada lọ́nà tí a ti là sílẹ̀ wọnyi, wọ́n gbọdọ̀ dá òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ọdún jubili.

55 Nítorí pé, iranṣẹ mi ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, iranṣẹ mi tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27