1 OLUWA ní kí Mose ati Aaroni
2 sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Nígbà tí nǹkan bá dà jáde lára ọkunrin, nǹkan tí ó jáde lára rẹ̀ yìí jẹ́ aláìmọ́.
3 Èyí sì ni òfin tí ó jẹmọ́ àìmọ́ rẹ̀, nítorí nǹkan tí ó ti ara rẹ̀ jáde; kì báà jẹ́ pé ó ń dà lọ́wọ́ lọ́wọ́, tabi ó ti dà tán, nǹkan tí ó dà yìí jẹ́ àìmọ́ lára rẹ̀.
4 Ibùsùn tí ẹni náà bá dùbúlẹ̀ lé lórí di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ pẹlu.
5 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
7 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
8 Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
9 Gàárì ẹṣin tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi gun ẹṣin di aláìmọ́.
10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
11 Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
12 Kí wọ́n fọ́ kòkò tí ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí bá fi ọwọ́ kàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun èlò onígi tí ó bá fọwọ́ kàn, wọ́n gbọdọ̀ fọ̀ wọn.
13 “Nígbà tí wọ́n bá sọ ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí di mímọ́ kúrò ninu ohun tí ó dà lára rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ meje fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ninu odò tí ó ń ṣàn; yóo sì di mímọ́.
14 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji, kí ó wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó sì kó wọn fún alufaa.
15 Alufaa yóo fi wọ́n rúbọ: yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Yóo ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ọkunrin náà, níwájú OLUWA.
16 “Kí ọkunrin tí nǹkan ọkunrin rẹ̀ bá dà sí lára, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ láti òkè dé ilẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
17 Gbogbo aṣọ ati awọ tí nǹkan ọkunrin náà bá dà sí gbọdọ̀ jẹ́ fífọ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
18 Bí ọkunrin bá bá obinrin lòpọ̀, tí nǹkan ọkunrin sì jáde lára rẹ̀, kí àwọn mejeeji wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
19 “Nígbà tí obinrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kàn án jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
20 Ohunkohun tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, tabi tí ó jókòó lé lórí ní gbogbo àkókò àìmọ́ rẹ̀ yóo di aláìmọ́.
21 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
22 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
23 Kì báà jẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni, tabi ohunkohun tí ó fi jókòó ni eniyan bá fi ara kàn, ẹni náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
24 Bí ọkunrin kan bá bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, ọkunrin náà yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, ibùsùn tí ọkunrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé lórí yóo jẹ́ aláìmọ́.
25 “Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
26 Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
28 Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́.
29 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
30 Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀.
31 “Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.”
32 Òfin yìí ni ó jẹmọ́ ti ọkunrin tí nǹkankan tabi nǹkan ọkunrin bá dà lára rẹ̀, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́;
33 ati obinrin tí ó ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ tabi tí nǹkan oṣù di àìsàn sí lára; ẹnikẹ́ni tí nǹkan bá sá ti ń dà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, ati ọkunrin tí ó bá bá obinrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ lòpọ̀.