Lefitiku 10 BM

Ẹ̀ṣẹ̀ Nadabu ati Abihu

1 Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn.

2 OLUWA bá rán iná kan jáde, iná náà jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLUWA.

3 Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀.

4 Mose bá pe Miṣaeli ati Elisafani, àwọn ọmọ Usieli, arakunrin Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ gbé òkú àwọn arakunrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́, kí ẹ sì gbé wọn jáde kúrò láàrin ibùdó.”

5 Wọ́n bá gbé wọn tẹ̀wù tẹ̀wù kúrò láàrin ibùdó gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí.

6 Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín.

7 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ẹ má baà kú, nítorí pé òróró ìyàsímímọ́ OLUWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.

Òfin fún Àwọn Alufaa

8 OLUWA bá Aaroni sọ̀rọ̀, ó ní,

9 “Nígbà tí o bá ń wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ, ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ẹ kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ má baà kú; èyí yóo jẹ́ ìlànà títí ayé fún arọmọdọmọ yín.

10 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀, láàrin ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati ohun tí ó wà fún ìlò gbogbo eniyan; ẹ níláti mọ ìyàtọ̀, láàrin àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ mímọ́ ati àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́;

11 ẹ sì níláti kọ́ àwọn eniyan Israẹli ní gbogbo ìlànà tí OLUWA ti là sílẹ̀, tí ó ní kí Mose sọ fun yín.”

12 Mose sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tí wọ́n ṣẹ́kù, Eleasari ati Itamari, ó ní, “Ẹ gbé ohun ìrúbọ tí ó kù ninu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA, kí ẹ sì jẹ ẹ́ lẹ́bàá pẹpẹ, láì fi ìwúkàrà sí i, nítorí pé mímọ́ jùlọ ni.

13 Ibi mímọ́ ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, nítorí pé òun ni ìpín yín ati ti àwọn ọmọ yín, ninu ẹbọ sísun OLUWA, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA pa á láṣẹ fún mi.

14 Ṣugbọn kí ẹ jẹ igẹ̀ tí ẹ bá fi rú ẹbọ fífì ati itan ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ní ibi mímọ́, ìwọ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn ọmọbinrin rẹ, nítorí pé ìpín tìrẹ ni, ati ti àwọn ọmọkunrin rẹ, ninu ẹbọ alaafia, tí àwọn eniyan Israẹli rú.

15 Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

16 Mose fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí nípa ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n ti dáná sun ún. Inú bí i sí Eleasari ati Itamari, àwọn ọmọ Aaroni tí wọ́n ṣẹ́kù, ó ní,

17 “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.

18 Wọn kò sì tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ.”

19 Aaroni dá Mose lóhùn pé, “Wò ó! Lónìí ni wọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun wọn sí OLUWA, sibẹsibẹ irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ǹjẹ́ ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA?”

20 Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ rọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27