Lefitiku 24 BM

Ìtọ́jú Àwọn Fìtílà

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún àtùpà ilé mímọ́ mi, kí ó lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.

3 Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín.

4 Aaroni yóo sì máa ṣe ìtọ́jú àwọn àtùpà tí wọ́n wà lórí ọ̀pá fìtílà wúrà, kí wọ́n lè máa wà ní títàn níwájú OLUWA nígbà gbogbo.

Àkàrà Tí Wọ́n Fi Rúbọ sí Ọlọrun

5 “Ẹ mú ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ẹ sì fi ṣe burẹdi mejila, ìdámárùn-ún ìwọ̀n ìyẹ̀fun efa kan ni kí ẹ fi ṣe burẹdi kọ̀ọ̀kan.

6 Ẹ sì máa tò wọ́n kalẹ̀ sí ọ̀nà meji; mẹfa mẹfa ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, lórí tabili tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe.

7 Ẹ fi ojúlówó turari sí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí àmì fún ìrántí.

8 Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae.

9 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ni àwọn burẹdi náà, ibi mímọ́ ni wọn yóo sì ti máa jẹ wọ́n, nítorí pé òun ni ó mọ́ jùlọ ninu ìpín wọn, ninu ọrẹ ẹbọ sísun sí OLUWA.”

Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ ati Ìjẹníyà Tí Ó Tọ́

10 Ọkunrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli, ṣugbọn tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ijipti. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli jáde, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun ati ọkunrin kan, tí ó jẹ́ ọmọ Israẹli, ní ibùdó.

11 Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani.

12 Wọ́n tì í mọ́lé títí tí wọn fi mọ ohun tí OLUWA fẹ́ kí wọ́n ṣe sí i.

13 OLUWA sọ fún Mose pé,

14 “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

15 Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.

16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.

17 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ẹlẹ́ran, yóo san án pada. Ohun tí ẹ̀tọ́ wí ni pé, kí á fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

19 “Bí ẹnìkan bá ṣá aládùúgbò rẹ̀ lọ́gbẹ́, irú ọgbẹ́ tí ó ṣá aládùúgbò rẹ̀ gan-an ni wọn yóo ṣá òun náà. Bí ẹnìkan bá ṣe aládùúgbò rẹ̀ léṣe, tí ó sì di ohun àbùkù sí i lára, ohun tí ó ṣe sí aládùúgbò rẹ̀ ni kí wọ́n ṣe sí òun náà.

20 Bí ó bá dá egungun aládùúgbò rẹ̀, kí wọ́n dá egungun tirẹ̀ náà, bí ó bá fọ́ ọ lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà, bí ó bá yọ eyín rẹ̀, kí wọ́n yọ eyín tirẹ̀ náà; irú ohun tí ó bá fi ṣe ẹlòmíràn gan-an ni kí wọn fi ṣe òun náà.

21 Ẹni tí ó bá pa ẹran, yóo san òmíràn pada, ẹni tí ó bá sì pa eniyan, wọn yóo pa òun náà.

22 Òfin kan náà tí ó de àlejò, ni ó gbọdọ̀ de onílé, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

23 Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27