1 “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀.
2 Kí ó gbé e tọ àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, lọ, kí alufaa náà bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ìyẹ̀fun náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀. Ẹ̀kúnwọ́ kan yìí ni alufaa yóo sun fún ìrántí, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLUWA.
3 Ohun tí ó ṣẹ́kù ninu ìyẹ̀fun náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ló mọ́ jùlọ, nítorí pé apá kan ninu ẹbọ sísun sí OLUWA ni.
4 “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu rẹ̀. Ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò ni wọ́n gbọdọ̀ fi yan án, ó sì lè jẹ́ burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu tí a da òróró lé lórí.
5 “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ó fi rúbọ, kí ó jẹ́ èyí tí ìyẹ̀fun rẹ̀ kúnná dáradára, tí a fi òróró pò, kí ó má sì ní ìwúkàrà ninu.
6 Já a sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró lé e lórí, ẹbọ ohun jíjẹ ni.
7 “Bí ẹbọ rẹ bá jẹ́ ti ohun jíjẹ tí a sè ninu ìkòkò, ìyẹ̀fun rẹ̀ gbọdọ̀ kúnná dáradára kí ó sì ní òróró.
8 Gbé àwọn ẹbọ ohun jíjẹ náà wá siwaju OLUWA. Nígbà tí o bá gbé e fún alufaa, yóo gbé e wá síbi pẹpẹ.
9 Alufaa yóo wá bu díẹ̀ ninu ẹbọ ohun jíjẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Ẹbọ tí a fi iná sun ni, tí ó ní òórùn dídùn tí inú OLUWA sì dùn sí.
10 Ohun tí ó bá ṣẹ́kù ninu ohun jíjẹ náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ni ó mọ́ jùlọ lára ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.
11 “Ẹbọ ohun jíjẹ tí o bá mú wá fún OLUWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà ninu, nítorí pé ìwúkàrà tabi oyin kò gbọdọ̀ sí ninu ẹbọ sísun sí OLUWA.
12 O lè mú wọn wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so oko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ bí ẹbọ olóòórùn dídùn.
13 Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ rẹ ni o gbọdọ̀ fi iyọ̀ sí, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ wọ́n ninu ọrẹ ohun jíjẹ rẹ; nítorí pé iyọ̀ ni ẹ̀rí majẹmu láàrin ìwọ pẹlu Ọlọrun rẹ, o níláti máa fi iyọ̀ sí gbogbo ẹbọ rẹ.
14 Bí o bá fẹ́ fi àkọ́so oko rẹ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí OLUWA, ninu ṣiiri ọkà àkọ́so oko rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ni kí o ti mú, kí o yan án lórí iná.
15 Da òróró sí i, kí o sì fi turari sórí rẹ̀. Ẹbọ ohun jíjẹ ni.
16 Alufaa yóo bù ninu ọkà pípa ati òróró náà, pẹlu gbogbo turari orí rẹ̀, yóo sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ìrántí. Ẹbọ sísun sí OLUWA ni.